(I'm not the original author, received via email from a friend)
MÚRA SÍ ISÉ RE ÒRÉÈ MI....Work hard, my friend
ISÉ NI A FI Í DI ENI GIGA....work is used to elevate one in respect and importance (Aspiring to higher heights is fully dependent on hard work)
BÍ A KÒ BÁ RÉNI FÈYÌN TÌ, BÍ ÒLE LÀ Á RÍ....if we do not have anyone to lean on, we appear indolent
BÍ A KO RÉNI GBÉKÈLÉ, À A TERA MÓ ISÉ ENI....if we do not have anyone to trust (we can depend on...), we simply work harder
ÌYÁ RE LÈ LÓWÓ LÓWÓ, BÀBÁ SÌ LÈ LÉSIN LÉÈKÀN....your mother may be wealthy, your father may have a ranch full of horses
BÍ O BÁ GBÓJÚ LÉ WON, O TÉ TÁN NI MO SO FÚN O....if you depend on their riches alone, you may end up in disgrace, I tell you
OHUN TÍ A KÒ BA JÌYÀ FÚN, KÌ Í LÈ TÓJÓ....whatever gain one does not work hard to earn usually does not last
OHUN TÍ A BÁ FARA SISÉ FÚN, NÍ Í PÉ LÓWÓ ENI....whatever gain one works hard to earn is the one that lasts in one's hands (while in ones possession)
APÁ LARÁ, ÌGÙNPÁ NÌYEKAN....the arm is a relative, the elbow is a sibling
BÍ AYÉ N FÉ O LÓNÌÍ. BÍ O BÁ LÓWÓ LÓWÓ NI WON Á MÁA FÉ O LÓLA....you may be loved by all today. it is when you have money that they will love you tomorrow
TÀBÍ TÍ O BÁ WÀ NÍ IPÒ , AYÉ Á YÉ O SÍ TÈRÍN-TÈRÍN....or when you are in a high position, all will honor you with cheers and smiles
JÉ KÍ O DI ENI N RÁÁGÓ KÍ O RÍ BÁYÉ TI Í SÍMÚ SÍ O....wait till you become poor or are struggling to get by and you will see how all grimace at you as they pass you by
ÈKÓ SÌ TÚN N SONI Í DÒGÁ; MÚRA KÍ O KÓ O DÁRADÁRA....education also elevates one in position; work hard to acquire good education
BÍ O SÌ RÍ ÒPÒ ÈNÌYÀN TÍ WÓN N FI ÈKÓ SE ÈRÍN RÍN, DÁKUN MÁ SE FARA WÉ WON - ÌYÀ N BÒ FÓMO TÍ KÒ GBÓN....and if you see a lot of people making education a laughing stock, please do not emulate or keep their company - suffering is lying in wait for an unserious kid
EKÚN N BE FÓMO TÓ N SÁ KIR....sorrow is in the reserve for a truant kid
MÁ FÒWÚRÒ SERÉ, ÒRÉÈ MI, MÚRA SÍSÉ, OJÓ N LO....do not play with your early years, my friend, work harder, time and tide wait for no one