(Received this and couldn't help telling it again :-)
Ni ojo kan , Baba Dare mu ere wa s'ile. Ere yi se pataki nitoriwipe o mo bi enia ba n pa'ro a si gba oluware l'eti.
Dare pada l'ati ile iwe, baba re si bere l'owo re idi t'o fi pe l'ati de'le.
Kaka ki o so otito, o ni awon nse'se asekun ni ile iwe ni.
Lai fi akoko s'ofo, ere yi gba Dare l'eti.
Baba re ran l'eti wipe ere yi se pataki o si mo bi enia ba n pa'ro a si gba onitohun l'eti.
Baba Dare: "Oya, so otito idi t'o fi pe de'le."
Dare: "Ba'mi, mo lo wo sinima ni."
Baba Dare: "Sinima wo?"
Dare: "Ofin mewa."
Lesekanna, Dare gba igba'ti oloyi.
Dare: "E da'rijimi ba'mi, mo lo wo sinima ibasepo aya oba."
Baba Dare: "O ye k'oju ti e iwo omo mi. N'igba ti mo wa ni ojo ori re emi o se awon nkan palapala wonyi".
L'oju ese, Baba Dare gba igba'ti l'owo ere.
Bi iya Dare ti gbo ohun ti oko re so, o jade wa l'ati ile ida'na, o si dahun pelu egan wipe, "sebi omo re ni Dare!!!!"
L'esekanna, ere yi sunmo iya Dare osi fun ni igbati oloyi.